Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 49:3nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    “Hu, ìwọ Heṣboni, nítorí Ai tí rún! Kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba! Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà, nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.

  2. Jeremiah 49:4nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ, ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso? Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ‘Ta ni yóò kò mí lójú?’

  3. Jeremiah 49:5nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  4. Jeremiah 49:6nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    “Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.

  5. Jeremiah 49:7nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

  6. Jeremiah 49:8nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani, nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau, ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.

  7. Jeremiah 49:9nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá; ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀? Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?

  8. Jeremiah 49:10nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò, èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn, nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́.

  9. Jeremiah 49:11nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”

  10. Jeremiah 49:12nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un.

  11. Jeremiah 49:13nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

  12. Jeremiah 49:14nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, a rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé, ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.

  13. Jeremiah 49:15nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.

  14. Jeremiah 49:16nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.

  15. Jeremiah 49:17nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    “Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ.

  16. Jeremiah 49:18nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní Olúwa wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

  17. Jeremiah 49:19nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    “Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

  18. Jeremiah 49:20nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Edomu, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde; pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.

  19. Jeremiah 49:21nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn, a ó gbọ́ igbe wọn ní Òkun pupa.

  20. Jeremiah 49:22nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀, yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.

  21. Jeremiah 49:23nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Nípa Damasku. “Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn, wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.

  22. Jeremiah 49:24nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Damasku di aláìlera, ó pẹ̀yìndà láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a; ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú, ìrora bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.

  23. Jeremiah 49:25nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀; ìlú tí mo dunnú sí.

  24. Jeremiah 49:26nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  25. Jeremiah 49:27nǹkan bí 583 ṣáájú Kristi

    “Èmi yóò fi iná sí odi Damasku, yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”