circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi, nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un, nígbà tí ó ti pa á láṣẹ láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”
- Jeremiah 48:1nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Nípa Moabu. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Ègbé ni fún Nebo nítorí a ó parun. A dójútì Kiriataimu, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.
- Jeremiah 48:2nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.
- Jeremiah 48:3nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Gbọ́ igbe ní Horonaimu, igbe ìrora àti ìparun ńlá.
- Jeremiah 48:4nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.
- Jeremiah 48:5nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Wọ́n gòkè lọ sí Luhiti, wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí Horonaimu igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.
- Jeremiah 48:6nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín; kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù.
- Jeremiah 48:7nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.
- Jeremiah 48:8nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
- Jeremiah 48:9nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Fi iyọ̀ sí Moabu, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.
- Jeremiah 48:10nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
“Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa, ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
- Jeremiah 48:11nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
“Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀, tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí. Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ, òórùn rẹ̀ kò yí padà.
- Jeremiah 48:12nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò tí wọ́n ó sì dà á síta; wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo, wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.
- Jeremiah 48:13nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi, bí ojú ti í ti ilé Israẹli nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.
- Jeremiah 48:14nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
“Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá, alágbára ní ogun jíjà’?
- Jeremiah 48:15nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀; a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,” ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
- Jeremiah 48:16nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
“Ìṣubú Moabu súnmọ́; ìpọ́njú yóò dé kánkán.
- Jeremiah 48:17nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó. Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’
- Jeremiah 48:18nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
“Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni, nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
- Jeremiah 48:19nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran, ìwọ tí ń gbé ní Aroeri. Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’
- Jeremiah 48:20nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Ojú ti Moabu nítorí tí a wó o lulẹ̀. Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe! Ẹ kéde rẹ̀ ní Arnoni pé, a pa Moabu run.
- Jeremiah 48:21nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ, sórí Holoni, Jahisa àti Mefaati,
- Jeremiah 48:22nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
sórí Diboni, Nebo àti Beti-Diblataimu,
- Jeremiah 48:23nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
sórí Kiriataimu, Beti-Gamu àti Beti-Meoni,
- Jeremiah 48:24nǹkan bí 584 ṣáájú Kristi
sórí Kerioti àti Bosra, sórí gbogbo ìlú Moabu, nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn.