Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 46:10nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn, títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀. Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.

  2. Jeremiah 46:11nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti. Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn, kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.

  3. Jeremiah 46:12nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ, igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé. Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ, àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”

  4. Jeremiah 46:13nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:

  5. Jeremiah 46:14nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli, sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi: ‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’

  6. Jeremiah 46:15nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú? Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.

  7. Jeremiah 46:16nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn. Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára.’

  8. Jeremiah 46:17nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé, ‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa, ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’

  9. Jeremiah 46:18nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.

  10. Jeremiah 46:19nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ nítorí Memfisi yóò di ahoro a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.

  11. Jeremiah 46:20nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé, ó dé láti àríwá.

  12. Jeremiah 46:21nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Àwọn jagunjagun rẹ̀ dàbí àbọ́pa akọ màlúù. Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà, wọn ó sì jùmọ̀ sá, wọn kò ní le dúró, nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà.

  13. Jeremiah 46:22nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára. Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.

  14. Jeremiah 46:23nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni Olúwa wí, “nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀. Nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.

  15. Jeremiah 46:24nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti, a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

  16. Jeremiah 46:25nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao.

  17. Jeremiah 46:26nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

  18. Jeremiah 46:27nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    “Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má fòyà, ìwọ Israẹli. Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò, kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.

  19. Jeremiah 46:28nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi

    Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí. Èmi kò ní run yín tán. Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo, èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”

  20. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa.

  21. Báyìí ni Olúwa wí: “Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá, wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀. Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀, ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn. Àwọn ènìyàn yóò kígbe, gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu

  22. nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá àti iye kẹ̀kẹ́ wọn. Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́; ọwọ́ wọn yóò kákò.

  23. Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé láti pa àwọn Filistini run, kí a sì mú àwọn tí ó là tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò. Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run, àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.

  24. Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀. A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́; ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

  25. “Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi? Padà sínú àkọ̀ rẹ; sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’