circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 44:20nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Wàyí o, Jeremiah sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé,
- Jeremiah 44:21nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“Ṣe Olúwa kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Juda àti àwọn ìgboro Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn baba rẹ, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú.
- Jeremiah 44:22nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Olúwa kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí.
- Jeremiah 44:23nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.”
- Jeremiah 44:24nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti.
- Jeremiah 44:25nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’ “Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.
- Jeremiah 44:26nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí, ‘pé kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra, “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.”
- Jeremiah 44:27nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán.
- Jeremiah 44:28nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Juda láti Ejibiti yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Juda, tí ó wá gbé ilẹ̀ Ejibiti yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí tiyín.
- Jeremiah 44:29nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
“ ‘Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’
- Jeremiah 44:30nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Farao Hofira ọba Ejibiti lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekiah ọba Juda lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”
- Jeremiah 45:1nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì sọ fún Baruku ọmọ Neriah ní ọdún kẹrin ti Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda. Lẹ́yìn tí Baruku ti kọ sínú ìwé kíká àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremiah ti ń sọ:
- Jeremiah 45:2nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ fún ọ, Baruku.
- Jeremiah 45:3nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ìwọ wí pé, ‘Ègbé ni fún mi! Olúwa ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora mi, àárẹ̀ mú mi nínú ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ìsinmi.’ ”
- Jeremiah 45:4nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Olúwa wí pé sọ èyí fún un, “Èyí ni Ọlọ́run sọ: ‘Èyí tí èmi ti kọ́ ni èmi yóò wò lulẹ̀, àti èyí tí èmi ti gbìn ni èmi yóò fàtu, àní ní orí gbogbo ilẹ̀.
- Jeremiah 45:5nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ṣé ìwọ sì ń wá ohun títóbi fún ara rẹ? Nítorí náà, má ṣe wá wọn. Èmi yóò mú ibi wá sí orí àwọn ènìyàn gbogbo ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n níbikíbi tí ìwọ bá lọ ni èmi yóò jẹ́ kí o sá àsálà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ.’ ”
- Jeremiah 46:1nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè.
- Jeremiah 46:2nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
- Jeremiah 46:3nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!
- Jeremiah 46:4nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ẹ di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún. Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àṣíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
- Jeremiah 46:5nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Kí ni nǹkan tí mo tún rí? Wọ́n bẹ̀rù, wọ́n sì ń padà sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun. Wọ́n sá, wọn kò sì bojú wẹ̀yìn, ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 46:6nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ, tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà. Ní àríwá ní ibi odò Eufurate wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
- Jeremiah 46:7nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti, tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?
- Jeremiah 46:8nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ejibiti dìde bí odò náà, bí omi odò tí ń ru. Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’ Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
- Jeremiah 46:9nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin, ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́. Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú, àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú; àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.