- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 930–586 BC
The Divided Kingdom
The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Ọba 15:27nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ní ọdún kejìléláàádọ́ta Asariah ọba Juda, Peka ọmọ Remaliah di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ogún ọdún.
- 2 Ọba 15:28nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá.
- 2 Ọba 15:29nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria.
- 2 Ọba 15:30nǹkan bí 739 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah.
- 2 Ọba 15:31nǹkan bí 739 ṣáájú Kristi
Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Peka, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
- 2 Ọba 15:32nǹkan bí 758 ṣáájú Kristi
Ní ọdún keje Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli, Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.
- 2 Ọba 15:33nǹkan bí 758 ṣáájú Kristi
Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìndínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku.
- 2 Ọba 15:34nǹkan bí 758 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Ussiah ti ṣe.
- 2 Ọba 15:35nǹkan bí 758 ṣáájú Kristi
Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò àwọn ènìyàn tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jotamu tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.
- 2 Ọba 15:36nǹkan bí 758 ṣáájú Kristi
Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jotamu, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
- 2 Ọba 15:37nǹkan bí 742 ṣáájú Kristi
(Ní ayé ìgbàanì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah láti dojúkọ Juda).
- 2 Ọba 15:38nǹkan bí 742 ṣáájú Kristi
Jotamu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi, ìlú ńlá ti baba rẹ̀. Ahasi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Ní ọdún kẹtàdínlógún Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ ọba.
Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jerusalẹmu, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀.
Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.
- 2 Ọba 16:5nǹkan bí 742 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.
- 2 Ọba 16:6nǹkan bí 742 ṣáájú Kristi
Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
- 2 Ọba 16:7nǹkan bí 742 ṣáájú Kristi
Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.”
- 2 Ọba 16:8nǹkan bí 742 ṣáájú Kristi
Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Asiria ní ọrẹ.
- 2 Ọba 16:9nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini.
- 2 Ọba 16:10nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.
- 2 Ọba 16:11nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku.
- 2 Ọba 16:12nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀.
- 2 Ọba 16:13nǹkan bí 740 ṣáájú Kristi
Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà.