Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Ọba 15:2nǹkan bí 810 ṣáájú Kristi

    Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jekoliah; ó wá láti Jerusalẹmu.

  2. 2 Ọba 15:3nǹkan bí 810 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe.

  3. 2 Ọba 15:4nǹkan bí 810 ṣáájú Kristi

    Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò, àwọn ènìyàn náà tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.

  4. 2 Ọba 15:5nǹkan bí 765 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jotamu, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

  5. 2 Ọba 15:6nǹkan bí 765 ṣáájú Kristi

    Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Asariah, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda.

  6. 2 Ọba 15:7nǹkan bí 758 ṣáájú Kristi

    Asariah sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dafidi. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  7. 2 Ọba 15:8nǹkan bí 773 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kejìdínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà.

  8. 2 Ọba 15:9nǹkan bí 773 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

  9. 2 Ọba 15:10nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀.

  10. 2 Ọba 15:11nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Sekariah. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

  11. 2 Ọba 15:12nǹkan bí 884 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jehu jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”

  12. 2 Ọba 15:13nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Ṣallumu ọmọ Jabesi di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ussiah ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún oṣù kan.

  13. 2 Ọba 15:14nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà Menahemu ọmọ Gadi lọ láti Tirsa sí Samaria. Ó dojúkọ Ṣallumu ọmọ Jabesi ní Samaria, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  14. 2 Ọba 15:15nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

  15. 2 Ọba 15:16nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.

  16. 2 Ọba 15:17nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kọkàndínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá.

  17. 2 Ọba 15:18nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

  18. 2 Ọba 15:19nǹkan bí 771 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, Pulu ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ náà, Menahemu sì fún un ní ẹgbẹ̀rin (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti fi gba àtìlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba.

  19. 2 Ọba 15:20nǹkan bí 771 ṣáájú Kristi

    Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.

  20. 2 Ọba 15:21nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Menahemu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Israẹli?

  21. 2 Ọba 15:22nǹkan bí 772 ṣáájú Kristi

    Menahemu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pekahiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  22. 2 Ọba 15:23nǹkan bí 761 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì.

  23. 2 Ọba 15:24nǹkan bí 761 ṣáájú Kristi

    Pekahiah ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá.

  24. 2 Ọba 15:25nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Peka ọmọ Remaliah, dìtẹ̀ sí i. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gileadi pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pekahiah pẹ̀lú Argobu àti Arie ní odi ààfin ọba ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni Peka pa Pekahiah, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  25. 2 Ọba 15:26nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi

    Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pekahiah, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.