Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 42:9nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu-ọ̀nà ní ìhà ìlà-oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.

  2. Esekiẹli 42:10nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ní ìhà gúúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà.

  3. Esekiẹli 42:11nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn

  4. Esekiẹli 42:12nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní yàrá tí òun ti ìlẹ̀kùn wọn ní ọ̀nà gúúsù, ìlẹ̀kùn kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà tí ó ṣe déédé pẹ̀lú ògiri tí ó gùn dé ìhà ìlà-oòrùn tí ènìyàn ń gba wọ inú àwọn yàrá.

  5. Esekiẹli 42:13nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ Olúwa yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́.

  6. Esekiẹli 42:14nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó súnmọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà.”

  7. Esekiẹli 42:15nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn agbègbè náà yípo:

  8. Esekiẹli 42:16nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ó wọn ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan; ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ìgbọ̀nwọ́.

  9. Esekiẹli 42:17nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá-ìwọ̀n nǹkan.

  10. Esekiẹli 42:18nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    O wọn ìhà gúúsù; ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan.

  11. Esekiẹli 42:19nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀-oòrùn o sì wọ̀n-ọ́n: ó sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n.

  12. Esekiẹli 42:20nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Báyìí ní ó wọ̀n-ọ́n ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi àìmọ́.

  13. Esekiẹli 43:1nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi gba ti ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn,

  14. Esekiẹli 43:2nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    mo sì ri ògo Ọlọ́run Israẹli ń bọ láti ìhà ìlà-oòrùn. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi, ìtànṣán ògo rẹ̀ sì bo ilẹ̀.

  15. Esekiẹli 43:3nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ó sì dàbí ìran tí mo rí, gẹ́gẹ́ bí ìran tí mo rí nígbà tí mo wá láti pa ìlú náà run; ìran náà sì dà bí ìran tí mo rí lẹ́bàá odò Kebari, mo sì dojú mi bolẹ̀.

  16. Esekiẹli 43:4nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ògo Olúwa gba ọ̀nà tí o dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn wọ inú ilé Ọlọ́run wá.

  17. Esekiẹli 43:5nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Mo ni ìrusókè ẹ̀mí, ó sì mú mi lọ inú ilé ìdájọ́, sì kíyèsi ògo Olúwa kún inú ilé Ọlọ́run.

  18. Esekiẹli 43:6nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ọkùnrin náà dúró ní ẹ̀gbẹ́ mi, mo gbọ́ ẹnìkan tí ó bá mi sọ̀rọ̀ láti inú ilé Ọlọ́run.

  19. Esekiẹli 43:7nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ibi ìgúnwà mi àti ibi tí ó wà fún àtẹ́lẹsẹ̀ mi. Ibi yìí ni èmi yóò máa gbé ní àárín àwọn ọmọ Israẹli títí láéláé. Ilé Israẹli kò ní ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́ láéláé àwọn tàbí àwọn ọba wọn nípa àgbèrè àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn ní ibi gíga.

  20. Esekiẹli 43:8nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n ba gbé ìloro ilé wọn kángun sí ìloro ilé mi àti ìlẹ̀kùn wọn sì ẹ̀gbẹ́ ìlẹ̀kùn mi, pẹ̀lú ògiri nìkan ní àárín èmi pẹ̀lú wọn, wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ìwà ìríra wọn. Nígbà náà ni mo pa wọ́n run ní ìbínú mi.

  21. Esekiẹli 43:9nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí jẹ́ kí wọn mú ìwà àgbèrè wọn àti àwọn ère aláìlẹ́mìí àwọn ọba wọn kúrò ni iwájú mi, èmi yóò sì gbé àárín wọn láéláé.

  22. Esekiẹli 43:10nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, ṣàpèjúwe ilé Ọlọ́run náà fún àwọn ènìyàn Israẹli kí ojú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, lè tì wọ́n sì jẹ́ kí wọn wo àwòrán ilé náà,

  23. Esekiẹli 43:11nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    tí ojú gbogbo ohun tí wọn ti ṣe bá tì wọ́n, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ àwòrán ilé Ọlọ́run náà bí wọ́n ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ, àbájáde àti àbáwọlé rẹ̀ gbogbo àwòrán àti gbogbo òfin àti ìlànà rẹ̀. Kọ ìwọ̀nyí sílẹ̀ ní iwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ́ olóòtítọ́ si àwòrán rẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀.

  24. Esekiẹli 43:12nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “Èyí yìí ní òfin ilé Ọlọ́run náà. Gbogbo àyíká lórí òkè gíga ní yóò jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ. Bí èyí ni òfin tẹmpili náà.

  25. Esekiẹli 43:13nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ̀nyí ni wíwọ̀n pẹpẹ ìrúbọ ní gígùn ìgbọ̀nwọ́, ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni jíjìn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìbú, igun rẹ̀ yípo àti etí rẹ̀ jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Èyí yìí sì ni gíga pẹpẹ ìrúbọ náà.