- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 44:12nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn níwájú àwọn ère wọn, tí wọn sì mu ilé Israẹli ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí náà, Èmi tí búra nípa nína ọwọ́ sókè pé, wọn gbọdọ̀ jèrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.
- Esekiẹli 44:13nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Wọn kò gbọdọ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi láti ṣe ìránṣẹ́ fún mi, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí súnmọ́ nǹkan kan nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ẹbọ mi mímọ́ jùlọ; wọn gbọdọ̀ gba ìtìjú ìwà ìríra wọn.
- Esekiẹli 44:14nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀ èmi yóò mu wọn sí ìtọ́jú ilé Ọlọ́run àti gbogbo iṣẹ́ tí a gbọdọ̀ ṣe níbẹ̀.
- Esekiẹli 44:15nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Lefi àti àwọn ìran Sadoku tí fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn gbọdọ̀ súnmọ́ iwájú láti ṣe ìránṣẹ́ ní iwájú mi, láti rú ẹbọ ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀, ni Olúwa Olódùmarè wí.
- Esekiẹli 44:16nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Àwọn nìkan ni ó gbọdọ̀ wọ ibi mímọ́ mi; àwọn nìkan ní o gbọdọ̀ súnmọ́ tábìlì mi láti ṣe ìránṣẹ́ ni iwájú mi, ki wọn sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mi.
- Esekiẹli 44:17nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Nígbà ti wọ́n wọ àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú, wọn yóò wọ ẹ̀wù ọ̀gbọ̀, wọn kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní àwọn ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tàbí ni inú ilé Ọlọ́run.
- Esekiẹli 44:18nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Wọ́n yóò sì dé fìlà ọ̀gbọ̀ sí orí wọn àti ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ sí ìdí wọn. Wọn kò sì gbọdọ̀ wọ ohunkóhun tí yóò mú wọn làágùn.
- Esekiẹli 44:19nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ ẹ̀wù mìíràn, wọn kì yóò sì fi ẹ̀wù wọn sọ àwọn ènìyàn di mímọ́.
- Esekiẹli 44:20nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Wọn kò gbọdọ̀ fá irun, wọn kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí irun wọn gùn, ṣùgbọ́n wọn gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn wà ní gígẹ̀.
- Esekiẹli 44:21nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú.
- Esekiẹli 44:22nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Wọn ko gbọdọ̀ fẹ́ opó ni ìyàwó, wọn kò sì gbọdọ̀ kọ ìyàwó wọn sílẹ̀, wọ́n lè fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ti kò tí i mọ ọkùnrin rí, tí ó sì jẹ́ ìran àwọn ọmọ Israẹli, tàbí kí wọn fẹ́ àwọn opó àlùfáà.
- Esekiẹli 44:23nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sì fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàrín mímọ́ àti àìmọ́ kọ́ àwọn ènìyàn mi, wọn yóò sì fihàn wọ́n bi wọn yóò ṣe dá aláìmọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí mímọ́.
- Esekiẹli 44:24nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Nínú èyíkéyìí èdè-àìyedè, àwọn àlùfáà ní yóò dúró gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin mi. Wọ́n ní láti pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́ ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn, wọn sì gbọdọ̀ ya ọjọ́ ìsinmi mi ní mímọ́.
- Esekiẹli 44:25nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nípa sísún mọ́ òkú ènìyàn; ṣùgbọ́n ti òkú ènìyàn yẹn bá jẹ́ baba tàbí ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin ti kò i ti lọ́kọ, nígbà náà o le sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́.
- Esekiẹli 44:26nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, ki òun kí ó dúró fún ọjọ́ méje.
- Esekiẹli 44:27nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti ṣe ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí ó rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.
- Esekiẹli 44:28nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Èmi ni yóò jẹ́ ogún kan ṣoṣo tí àwọn àlùfáà yóò ní. Ẹ kì yóò fún wọn ni ìpín kankan ní Israẹli, Èmi ni yóò jẹ́ ìní wọn.
- Esekiẹli 44:29nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Israẹli ni yóò jẹ́ tiwọn.
- Esekiẹli 44:30nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ọrẹ yín yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ó sì fi àkọ́pò ìyẹ̀fun yín fún wọn kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yín.
- Esekiẹli 44:31nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Àwọn àlùfáà kì yóò jẹ́ ohunkóhun bí i ẹyẹ tàbí ẹranko, tí ó ti kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí ti ẹranko ńlá fàya.
- Esekiẹli 45:1nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́.
- Esekiẹli 45:2nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Lára inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) yóò jẹ́ ti ibi mímọ́ ní gígùn, pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ìbú, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yíká, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún gbangba rẹ̀ yíká.
- Esekiẹli 45:3nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ìbú. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn Ibi Mímọ́ Jùlọ.
- Esekiẹli 45:4nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa.
- Esekiẹli 45:5nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ní ìbú yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.