- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 46:6nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n.
- Esekiẹli 46:7nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan.
- Esekiẹli 46:8nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.
- Esekiẹli 46:9nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.
- Esekiẹli 46:10nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.
- Esekiẹli 46:11nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan.
- Esekiẹli 46:12nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un. Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.
- Esekiẹli 46:13nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀.
- Esekiẹli 46:14nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí.
- Esekiẹli 46:15nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.
- Esekiẹli 46:16nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
“ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ, tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ.
- Esekiẹli 46:17nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀, lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn.
- Esekiẹli 46:18nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”
- Esekiẹli 46:19nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bàá ẹnu-ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀-oòrùn.
- Esekiẹli 46:20nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má ṣe jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá, kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”
- Esekiẹli 46:21nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan.
- Esekiẹli 46:22nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnu pọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà.
- Esekiẹli 46:23nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ní agbègbè inú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo.
- Esekiẹli 46:24nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”
- Esekiẹli 47:1nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹmpili náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹmpili náà sí apá ìhà ìlà-oòrùn (nítorí tẹmpili náà dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn). Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúúsù tẹmpili náà, ní ìhà gúúsù pẹpẹ.
- Esekiẹli 47:2nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, omi náà sì ń sàn láti ìhà gúúsù wá.
- Esekiẹli 47:3nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, ó wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kò jì jù kókósẹ̀ lọ.
- Esekiẹli 47:4nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí.
- Esekiẹli 47:5nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni.
- Esekiẹli 47:6nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi
Ó bi mí léèrè pé, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?” Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò.