Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 45:6nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Israẹli.

  2. Esekiẹli 45:7nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn ọmọ-aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbègbè tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn láti apá ìwọ̀-oòrùn àti si ìlà-oòrùn, láti apá ìlà-oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀-oòrùn sí ààlà ìlà-oòrùn, ti ìṣe déédé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà.

  3. Esekiẹli 45:8nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.

  4. Esekiẹli 45:9nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí.

  5. Esekiẹli 45:10nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Kí ẹ̀yin kì ó lo òsùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́.

  6. Esekiẹli 45:11nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Efa àti bati gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bati tí ó gba ìdámẹ́wàá homeri, àti efa ìdámẹ́wàá homeri: Homeri ni kí ó jẹ́ òsùwọ̀n tí ẹ̀yin yóò lò fún méjèèjì.

  7. Esekiẹli 45:12nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ mina kan.

  8. Esekiẹli 45:13nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ gbọdọ̀ ṣe: efa kẹfà láti inú homeri ọkà kọ̀ọ̀kan àti efa kẹfà láti inú homeri barle kọ̀ọ̀kan.

  9. Esekiẹli 45:14nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bati wọ́n, ni ìdámẹ́wàá bati láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí homeri kan, fún ìdámẹ́wàá bati jẹ́ bákan náà sì homeri kan).

  10. Esekiẹli 45:15nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí.

  11. Esekiẹli 45:16nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli.

  12. Esekiẹli 45:17nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.

  13. Esekiẹli 45:18nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́.

  14. Esekiẹli 45:19nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú.

  15. Esekiẹli 45:20nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ keje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.

  16. Esekiẹli 45:21nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà.

  17. Esekiẹli 45:22nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà.

  18. Esekiẹli 45:23nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

  19. Esekiẹli 45:24nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.

  20. Esekiẹli 45:25nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Láàrín ọjọ́ méje àsè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, òun yóò tún pèsè ohun kan náà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, àti fún òróró.

  21. Esekiẹli 46:1nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí, ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i.

  22. Esekiẹli 46:2nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́.

  23. Esekiẹli 46:3nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà.

  24. Esekiẹli 46:4nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.

  25. Esekiẹli 46:5nǹkan bí 574 ṣáájú Kristi

    Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan.