Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 27:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.

  2. Esekiẹli 27:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

  3. Esekiẹli 27:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

  4. Esekiẹli 27:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Damasku ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari,

  5. Esekiẹli 27:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ.

  6. Esekiẹli 27:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

  7. Esekiẹli 27:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé ìlú Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ; ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.

  8. Esekiẹli 27:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

  9. Esekiẹli 27:23nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ.

  10. Esekiẹli 27:24nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

  11. Esekiẹli 27:25nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò ní ọjà rẹ a ti mú ọ gbilẹ̀ a sì ti ṣe ọ́ lógo ní àárín gbùngbùn Òkun.

  12. Esekiẹli 27:26nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú omi ńlá. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ ní àárín gbùngbùn Òkun.

  13. Esekiẹli 27:27nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ, àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ. Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ, àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ tí ó wà ní àárín rẹ yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun ní ọjọ́ ìparun rẹ.

  14. Esekiẹli 27:28nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.

  15. Esekiẹli 27:29nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn alájẹ̀, àwọn atukọ̀ Òkun àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun; yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.

  16. Esekiẹli 27:30nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.

  17. Esekiẹli 27:31nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ wọn yóò wọ aṣọ yíya wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú ìkorò ọkàn nítorí rẹ pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.

  18. Esekiẹli 27:32nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé: “Ta ni ó dàbí Tire èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”

  19. Esekiẹli 27:33nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

  20. Esekiẹli 27:34nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi; nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárín rẹ, ni yóò ṣubú.

  21. Esekiẹli 27:35nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn, ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.

  22. Esekiẹli 27:36nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

  23. Esekiẹli 28:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:

  24. Esekiẹli 28:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.

  25. Esekiẹli 28:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?