- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 26:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀.
- Esekiẹli 26:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun.
- Esekiẹli 26:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́.
- Esekiẹli 26:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.
- Esekiẹli 26:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ?
- Esekiẹli 26:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.
- Esekiẹli 26:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé: “ ‘Báwo ni a ṣe pa ọ́ run, ìwọ ìlú olókìkí ìwọ tí àwọn èrò okun ti gbé inú rẹ̀! Ìwọ jẹ alágbára lórí okun gbogbo òun àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; ìwọ gbé ẹ̀rù rẹ lórí gbogbo olùgbé ibẹ̀.
- Esekiẹli 26:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí erékùṣù wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ; erékùṣù tí ó wà nínú Òkun ni ẹ̀rù bà torí ìṣubú rẹ.’
- Esekiẹli 26:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́,
- Esekiẹli 26:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
- Esekiẹli 26:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
- Esekiẹli 27:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé:
- Esekiẹli 27:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tire.
- Esekiẹli 27:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ìwọ Tire wí pé, “Ẹwà mi pé.”
- Esekiẹli 27:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun; àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.
- Esekiẹli 27:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ ní igi junifa láti Seniri; wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.
- Esekiẹli 27:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nínú igi óákù ti Baṣani ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀; ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá.
- Esekiẹli 27:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ; aṣọ aláró àti elése àlùkò láti erékùṣù ti Eliṣa ni èyí tí a fi bò ó.
- Esekiẹli 27:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire, ni àwọn atukọ̀ rẹ.
- Esekiẹli 27:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn àgbàgbà Gebali, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun àti àwọn atukọ̀ Òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
- Esekiẹli 27:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn.
- Esekiẹli 27:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki wà lórí odi rẹ yíká; àti àwọn akọni Gamadi, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ. Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ; wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
- Esekiẹli 27:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
- Esekiẹli 27:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ, wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.
- Esekiẹli 27:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.