Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 25:3nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Sì wí fún àwọn ará Ammoni pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè tí ó wí pé. Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Israẹli nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Juda, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,

  2. Esekiẹli 25:4nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    kíyèsi i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ, wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.

  3. Esekiẹli 25:5nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì sọ Rabba di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasẹ àti àwọn ọmọ Ammoni di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  4. Esekiẹli 25:6nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Nítorí báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Israẹli

  5. Esekiẹli 25:7nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

  6. Esekiẹli 25:8nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí pé Moabu àti Seiri sọ wí pé, “Wò ó, ilé Juda ti dàbí gbogbo àwọn kèfèrí,”

  7. Esekiẹli 25:9nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    nítorí náà, Èmi yóò ṣí Moabu sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Beti-Jeṣimoti, Baali-Meoni àti Kiriataimu.

  8. Esekiẹli 25:10nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fi Moabu pẹ̀lú àwọn ará Ammoni lé àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ammoni láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

  9. Esekiẹli 25:11nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì mú ìdájọ́ sẹ sí Moabu lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’ ”

  10. Esekiẹli 25:12nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí pé Edomu gbẹ̀san lára ilé Juda, ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀,

  11. Esekiẹli 25:13nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Edomu èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi ṣófo láti Temani dé Dedani yóò ti ipa idà ṣubú.

  12. Esekiẹli 25:14nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò gbẹ̀san lára Edomu láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Israẹli, wọn sì ṣe sí Edomu gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi, wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

  13. Esekiẹli 25:15nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí tí àwọn ará Filistini hùwà ẹ̀san tí wọ́n sì gbẹ̀san pẹ̀lú odì ní ọkàn wọn, àti pẹ̀lú ìkórìíra gbangba àtijọ́ ní wíwá ọ̀nà láti pa Juda run,

  14. Esekiẹli 25:16nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé, “Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Filistini, èmi yóò sì ké àwọn ará Kereti kúrò, èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run.

  15. Esekiẹli 25:17nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni Olúwa. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.” ’ ”

  16. Esekiẹli 26:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kọ́kànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  17. Esekiẹli 26:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’

  18. Esekiẹli 26:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè.

  19. Esekiẹli 26:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.

  20. Esekiẹli 26:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

  21. Esekiẹli 26:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  22. Esekiẹli 26:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    “Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun.

  23. Esekiẹli 26:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ.

  24. Esekiẹli 26:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.

  25. Esekiẹli 26:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá.