Fò sí àkóónú

circa 605–538 BC

The Babylonian Exile

Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.

1,784 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Esekiẹli 23:29nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò fìyà jẹ ọ́ pẹ̀lú ìkórìíra, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí o ṣiṣẹ́ fún lọ. Wọn yóò fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòhò goloto, ìtìjú iṣẹ́ panṣágà rẹ ni yóò farahàn. Ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti panṣágà rẹ.

  2. Esekiẹli 23:30nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí sí ọ, nítorí ìwọ ti bá àwọn kèfèrí ṣe àgbèrè lọ, o sì fi àwọn òrìṣà wọn ba ara rẹ̀ jẹ́.

  3. Esekiẹli 23:31nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ti rin ọ̀nà ti ẹ̀gbọ́n rẹ rìn, Èmi yóò sì fi ago rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.

  4. Esekiẹli 23:32nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Èyí yìí ní ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ yóò mu nínú ago ẹ̀gbọ́n rẹ, ago tí ó tóbi tí ó sì jinnú: yóò mú ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣe ẹlẹ́yà wá, nítorí tí ago náà gba nǹkan púpọ̀.

  5. Esekiẹli 23:33nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò mu àmupara àti ìbànújẹ́, ago ìparun àti ìsọdahoro ago ẹ̀gbọ́n rẹ Samaria.

  6. Esekiẹli 23:34nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò mú un ni àmugbẹ; ìwọ yóò sì fọ sí wẹ́wẹ́ ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ̀ ya. Èmi ti sọ̀rọ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.

  7. Esekiẹli 23:35nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Níwọ́n bí ìwọ ti gbàgbé mi, tí ìwọ sì ti fi mi sí ẹ̀yìn rẹ, ìwọ gbọdọ̀ gba àbájáde ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti panṣágà rẹ.”

  8. Esekiẹli 23:36nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Ohola àti Oholiba? Nítorí náà dojúkọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe,

  9. Esekiẹli 23:37nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fún ni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn.

  10. Esekiẹli 23:38nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi. Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́.

  11. Esekiẹli 23:39nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkulò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.

  12. Esekiẹli 23:40nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀ṣọ́ iyebíye sára.

  13. Esekiẹli 23:41nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà.

  14. Esekiẹli 23:42nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú àwọn ara Sabeani láti aginjù pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dáradára sì wà ní orí wọn.

  15. Esekiẹli 23:43nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà mo sọ̀rọ̀ nípa èyí tí ó lo ara rẹ̀ sá nípa panṣágà ṣíṣe, ‘Nísinsin yìí jẹ kí wọn lo o bí panṣágà, nítorí gbogbo ohun tí ó jẹ́ nìyẹn.’

  16. Esekiẹli 23:44nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Wọn ba sùn bí ọkùnrin ti bá panṣágà sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sùn pẹ̀lú obìnrin onífẹ̀kúfẹ̀ẹ́, Ohola àti Oholiba.

  17. Esekiẹli 23:45nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin olódodo yóò pàṣẹ pé kí wọ́n fi ìyà jẹ àwọn obìnrin tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè tí ó sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé panṣágà ni wọ́n ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn.

  18. Esekiẹli 23:46nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Mú àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn wá sọ́dọ̀ wọn ki ó sì fi wọn lé ọwọ́ ìpayà àti ìkógun.

  19. Esekiẹli 23:47nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyànkénìyàn náà yóò sọ wọ́n ni òkúta, yóò sì gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà wọn; wọn ó sì pa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n ó sì jó àwọn ilé wọn kanlẹ̀.”

  20. Esekiẹli 23:48nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    “Èmi yóò sì fi òpin sí ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ni ilẹ̀ náà, kí gbogbo àwọn obìnrin le gba ìkìlọ̀ kí wọn kí ó ma sì ṣe fi ara wé ọ.

  21. Esekiẹli 23:49nǹkan bí 593 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò sì jìyà fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì gba àbájáde àwọn ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí o dá. Nígbà náà ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.”

  22. Esekiẹli 24:1nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹsànán, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:

  23. Esekiẹli 24:2nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    “Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí ọba Babeli náà ti da ojú ti Jerusalẹmu ní ọjọ́ yìí gan an.

  24. Esekiẹli 24:3nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná, gbé e ka iná kí o sì da omi sí i nínú.

  25. Esekiẹli 24:4nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi

    Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀, gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá. Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀,