- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Esekiẹli 24:5nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran. Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀; sì jẹ́ kí ó hó dáradára sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.
- Esekiẹli 24:6nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà, fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀, tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀! Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí má ṣe ṣà wọ́n mú.
- Esekiẹli 24:7nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
“ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárín rẹ̀; à á sí orí àpáta kan lásán kò dà á sí orí ilẹ̀, níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó.
- Esekiẹli 24:8nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán, kí o ma bà á wà ni bíbò.
- Esekiẹli 24:9nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Nítorí náà báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà! Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi.
- Esekiẹli 24:10nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Nítorí náà kó igi náà jọ sí i, kí o sì fi iná sí i. Ṣe ẹran náà dáradára, fi tùràrí dùn ún; kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná.
- Esekiẹli 24:11nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n àti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀ kí èérí rẹ̀ le jó dànù.
- Esekiẹli 24:12nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ: èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀, èérí náà gan an yóò wà nínú iná.
- Esekiẹli 24:13nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
“ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.
- Esekiẹli 24:14nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
- Esekiẹli 24:15nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá pé:
- Esekiẹli 24:16nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, kíyèsi i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀.
- Esekiẹli 24:17nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Má ṣe sọkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ, má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”
- Esekiẹli 24:18nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàṣẹ fún mi.
- Esekiẹli 24:19nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”
- Esekiẹli 24:20nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
- Esekiẹli 24:21nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Sọ fún ilé Israẹli, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ tayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáàánú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà.
- Esekiẹli 24:22nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.
- Esekiẹli 24:23nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedéédéé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrín ara yín.
- Esekiẹli 24:24nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Esekiẹli yóò jẹ àmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’
- Esekiẹli 24:25nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
“Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn,
- Esekiẹli 24:26nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ.
- Esekiẹli 24:27nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì ṣí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ àmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní Olúwa.”
- Esekiẹli 25:1nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
- Esekiẹli 25:2nǹkan bí 590 ṣáájú Kristi
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ammoni kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn.