- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 28:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elése àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.
- Eksodu 28:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Wọn yóò sì dá ẹ̀wù efodu ti wúrà, tí aṣọ aláró, elése àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, iṣẹ́ ọlọ́nà.
- Eksodu 28:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀.
- Eksodu 28:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́.
- Eksodu 28:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkìsì méjì, ìwọ yóò sì fín orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sára wọn.
- Eksodu 28:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì.
- Eksodu 28:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà.
- Eksodu 28:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká efodu náà ní òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Aaroni yóò sì máa ní orúkọ wọn níwájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.
- Eksodu 28:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà,
- Eksodu 28:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.
- Eksodu 28:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinnu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà. Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù efodu ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára.
- Eksodu 28:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé—kí ó jẹ́ ìwọ̀n ìka kan ní ìnà àti ìwọ̀n ìka kan ní ìbú, kí o sì ṣe é ní ìṣẹ́po méjì.
- Eksodu 28:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta oníyebíye mẹ́rin sára ẹsẹ̀ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, topasi àti berili wà;
- Eksodu 28:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ní ẹsẹ̀ kejì turikuose, emeradi, safire, àti diamọndi;
- Eksodu 28:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ní ẹsẹ̀ kẹta, jasiniti, agate, àti ametisiti;
- Eksodu 28:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ní ẹsẹ̀ kẹrin, topasi, àti óníkìsì àti jasperi. A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn.
- Eksodu 28:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Òkúta méjìlá yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
- Eksodu 28:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Fún ìgbàyà náà, ìwọ yóò ṣe okùn ẹ̀wọ̀n ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè.
- Eksodu 28:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì fún un, kí o sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà.
- Eksodu 28:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì mọ́ òrùka ní igun ìgbàyà náà,
- Eksodu 28:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
àti etí ẹ̀wọ̀n méje ni kí o so mọ́ ojú ìdè méjèèjì, kí o sì fi sí èjìká ẹ̀wù efodu náà níwájú.
- Eksodu 28:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì so wọ́n mọ́ igun méjì ìgbàyà kejì ní ìhà inú tí ó ti ẹ̀wù efodu náà.
- Eksodu 28:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù efodu méjèèjì ní ìsàlẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó súnmọ́ ojú sí ìránṣọ náà, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu náà.
- Eksodu 28:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù efodu pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù efodu náà.
- Eksodu 28:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Nígbàkígbà tí Aaroni bá wọ Ibi Mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinnu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa.