- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 27:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò sì kọ pẹpẹ igi kasia kan, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gígùn; kí ìhà rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ìwọ̀n kan, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀.
- Eksodu 27:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò ṣì ṣe ìwo orí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ.
- Eksodu 27:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì ṣe abọ́ ìtẹ́dìí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe.
- Eksodu 27:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, iṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin iṣẹ́ àwọ̀n náà.
- Eksodu 27:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà.
- Eksodu 27:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kasia fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ.
- Eksodu 27:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú.
- Eksodu 27:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì ṣe pákó náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fihàn ọ́ ní orí òkè.
- Eksodu 27:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò sì ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúúsù, ó gbọdọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mita mẹ́rìndínláàádọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́,
- Eksodu 27:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
pẹ̀lú ogún òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú.
- Eksodu 27:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun òpó àti ogún ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
- Eksodu 27:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.
- Eksodu 27:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ní ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀.
- Eksodu 27:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu-ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
- Eksodu 27:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.
- Eksodu 27:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Àti fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà, pèsè aṣọ títa, mita mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elése àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.
- Eksodu 27:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.
- Eksodu 27:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Àgbàlá náà yóò jẹ́ mita mẹ́rìndínláàádọ́ta ni gíga àti mita mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mita méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.
- Eksodu 27:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.
- Eksodu 27:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀.
- Eksodu 27:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde aṣọ ìkélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Aaroni àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ láti alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú Olúwa: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.
- Eksodu 28:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
- Eksodu 28:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá.
- Eksodu 28:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Aaroni, fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
- Eksodu 28:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù efodu, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Aaroni arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.