- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 26:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì, èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó.
- Eksodu 26:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì ṣe ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.
- Eksodu 26:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà.
- Eksodu 26:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀.
- Eksodu 26:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.
- Eksodu 26:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ ó sì ṣe ogún pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà,
- Eksodu 26:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ìwọ ó sì ṣe ogójì ìhà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìsàlẹ̀ wọn. Méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.
- Eksodu 26:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó síbẹ̀
- Eksodu 26:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan.
- Eksodu 26:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí ìwọ kí ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà,
- Eksodu 26:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
kí o sì ṣe pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn.
- Eksodu 26:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ní igun méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bákan náà.
- Eksodu 26:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Wọn ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.
- Eksodu 26:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà,
- Eksodu 26:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà.
- Eksodu 26:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà.
- Eksodu 26:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.
- Eksodu 26:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ́ lórí òkè.
- Eksodu 26:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é.
- Eksodu 26:32nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin.
- Eksodu 26:33nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà Ibi Mímọ́ kúrò ní Ibi Mímọ́ Jùlọ.
- Eksodu 26:34nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni Ibi Mímọ́ Jùlọ.
- Eksodu 26:35nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fìtílà sí òdìkejì rẹ̀ ní ìhà àríwá.
- Eksodu 26:36nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Fún ti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe.
- Eksodu 26:37nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ ó sì ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, àti òpó igi ṣittimu márùn-ún tí a sì fi wúrà bò. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ márùn-ún fún wọn.