Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 8:19nǹkan bí 1112 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa?

  2. 1 Samuẹli 8:20nǹkan bí 1112 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”

  3. 1 Samuẹli 8:21nǹkan bí 1112 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa.

  4. 1 Samuẹli 8:22nǹkan bí 1112 ṣáájú Kristi

    Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.” Nígbà náà, Samuẹli sọ fún àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”

  5. 1 Samuẹli 9:1nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Ará Benjamini kan wà, ẹni tí ó jẹ́ aláàánú ọlọ́rọ̀, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afiah ti Benjamini.

  6. 1 Samuẹli 9:2nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Saulu, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàrín gbogbo àwọn ọmọ Israẹli—láti èjìká rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn tókù lọ.

  7. 1 Samuẹli 9:3nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kiṣi baba Saulu sì sọnù. Nígbà náà, Kiṣi sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”

  8. 1 Samuẹli 9:4nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn.

  9. 1 Samuẹli 9:5nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”

  10. 1 Samuẹli 9:6nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ síbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a yóò gbà.”

  11. 1 Samuẹli 9:7nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Saulu sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?”

  12. 1 Samuẹli 9:8nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Ìránṣẹ́ sì dá a lóhùn lẹ́ẹ̀kan sí i. “Wò ó,” ó wí pé, “Mo ní ìdámẹ́rin ṣékélì fàdákà lọ́wọ́. Èmi yóò fún ènìyàn Ọlọ́run náà kí ó lè fi ọ̀nà hàn wá.”

  13. 1 Samuẹli 9:9nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    (Tẹ́lẹ̀ ní Israẹli tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìsinsin yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì).

  14. 1 Samuẹli 9:10nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Saulu sọ fún ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ pé ó dára, “Jẹ́ kí a lọ.” Wọ́n jáde lọ sí ìlú tí ènìyàn Ọlọ́run náà ń gbé.

  15. 1 Samuẹli 9:11nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n ṣe ń lọ ní orí òkè sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tí ó ń jáde í bọ̀ láti wá pọn omí. Wọ́n sì bi wọ́n, “Ṣé wòlíì náà wà níbí?”

  16. 1 Samuẹli 9:12nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    “Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsin yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.

  17. 1 Samuẹli 9:13nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbọdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsin yìí, ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”

  18. 1 Samuẹli 9:14nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.

  19. 1 Samuẹli 9:15nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Olúwa ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé,

  20. 1 Samuẹli 9:16nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

  21. 1 Samuẹli 9:17nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Samuẹli fojúrí Saulu, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”

  22. 1 Samuẹli 9:18nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Saulu sì súnmọ́ Samuẹli ní ẹnu-ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

  23. 1 Samuẹli 9:19nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Samuẹli dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ.

  24. 1 Samuẹli 9:20nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Fún ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sọnù fún ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn, má ṣe dààmú nípa wọ́n: a ti rí wọn. Sí ta ni gbogbo ìfẹ́ Israẹli wà? Bí kì í ṣe sí ìwọ àti sí gbogbo ilé baba à rẹ.”

  25. 1 Samuẹli 9:21nǹkan bí 1095 ṣáájú Kristi

    Saulu dáhùn pé, “Ṣùgbọ́n èmi kì í há ṣe ẹ̀yà Benjamini? Kékeré nínú ẹ̀yà Israẹli. Ìdílé mi kò ha rẹ̀yìn jùlọ nínú gbogbo ẹ̀yà Benjamini? Èéṣì ti ṣe tí ìwọ sọ̀rọ̀ yìí sí mi?”