Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 20:33nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni.

  2. 1 Samuẹli 20:34nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í.

  3. 1 Samuẹli 20:35nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jonatani jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dafidi ti fi àdéhùn sí, ọmọdékùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀.

  4. 1 Samuẹli 20:36nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀.

  5. 1 Samuẹli 20:37nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jonatani ta, Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”

  6. 1 Samuẹli 20:38nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jonatani sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá.

  7. 1 Samuẹli 20:39nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    (Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jonatani àti Dafidi ni ó mọ ọ̀ràn náà.)

  8. 1 Samuẹli 20:40nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Jonatani sì fi apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú.”

  9. 1 Samuẹli 20:41nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Bí ọmọdékùnrin náà ti lọ tán, Dafidi sì dìde láti ibi ìhà gúúsù òkúta náà, ó sì wólẹ̀, ó sì tẹríba ní ìdojúbolẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jonatani, wọ́n sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì jùmọ̀ sọkún, èkínní pẹ̀lú èkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi sọkún púpọ̀ jù.

  10. 1 Samuẹli 20:42nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Jonatani sì wí fún Dafidi pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, bí o ti jẹ́ pé àwa méjèèjì tí jùmọ̀ búra ni orúkọ Olúwa pé, ‘Ki Olúwa ó wà láàrín èmi àti ìwọ, láàrín irú-ọmọ mi àti láàrín irú-ọmọ rẹ̀ láéláé.’ ” Òun sì dìde, ó sì lọ kúrò: Jonatani sì lọ sí ìlú.

  11. 1 Samuẹli 21:1nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?”

  12. 1 Samuẹli 21:2nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.

  13. 1 Samuẹli 21:3nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.”

  14. 1 Samuẹli 21:4nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́. Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”

  15. 1 Samuẹli 21:5nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!”

  16. 1 Samuẹli 21:6nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fi àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn níbẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.

  17. 1 Samuẹli 21:7nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dádúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Doegi, ará Edomu olórí nínú àwọn darandaran Saulu.

  18. 1 Samuẹli 21:8nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì tún wí fún Ahimeleki pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn-ín? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.”

  19. 1 Samuẹli 21:9nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.” Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”

  20. 1 Samuẹli 21:10nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

  21. 1 Samuẹli 21:11nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?”

  22. 1 Samuẹli 21:12nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Akiṣi ọba Gati gidigidi.

  23. 1 Samuẹli 21:13nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.

  24. 1 Samuẹli 21:14nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Akiṣi wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá.

  25. 1 Samuẹli 21:15nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Mo ha ni un fi aṣiwèrè ṣe? Tí ẹ̀yin fi mú èyí tọ̀ mí wá láti hu ìwà aṣiwèrè níwájú mi? Eléyìí yóò ha wọ inú ilé mi?”