Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 22:1nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀.

  2. 1 Samuẹli 22:2nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin.

  3. 1 Samuẹli 22:3nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mispa tí Moabu: ó sì wí fún ọba Moabu pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.”

  4. 1 Samuẹli 22:4nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ó sì mú wọn wá síwájú ọba Moabu; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dafidi fi wà nínú ihò náà.

  5. 1 Samuẹli 22:5nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Gadi wòlíì sí wí fún Dafidi pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Juda.” Nígbà náà ni Dafidi sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hereti.

  6. 1 Samuẹli 22:6nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í.

  7. 1 Samuẹli 22:7nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí?

  8. 1 Samuẹli 22:8nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

  9. 1 Samuẹli 22:9nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu.

  10. 1 Samuẹli 22:10nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”

  11. 1 Samuẹli 22:11nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba.

  12. 1 Samuẹli 22:12nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.” Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.”

  13. 1 Samuẹli 22:13nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

  14. 1 Samuẹli 22:14nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ.

  15. 1 Samuẹli 22:15nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.”

  16. 1 Samuẹli 22:16nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”

  17. 1 Samuẹli 22:17nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.

  18. 1 Samuẹli 22:18nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu.

  19. 1 Samuẹli 22:19nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.

  20. 1 Samuẹli 22:20nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu tí a ń pè ní Abiatari sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dafidi lọ.

  21. 1 Samuẹli 22:21nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Abiatari sì fihan Dafidi pé Saulu pa àwọn àlùfáà Olúwa tán.

  22. 1 Samuẹli 22:22nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Dafidi sì wí fún Abiatari pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Doegi ará Edomu ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Saulu: nítorí mi ni a ṣe pa gbogbo ìdílé baba rẹ.

  23. 1 Samuẹli 22:23nǹkan bí 1062 ṣáájú Kristi

    Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”

  24. Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.”

  25. Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?” Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.”