Fò sí àkóónú

circa 1406–1380 BC

Conquest of Canaan

Joshua leads Israel across the Jordan into the promised land, defeating the Canaanite kingdoms one by one.

658 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Joṣua 11:20nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Israẹli jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátápátá, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  2. Joṣua 11:21nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Ní àkókò náà ni Joṣua lọ tí ó sì run àwọn ará Anaki kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hebroni, Debiri, àti ní Anabu, àti gbogbo ilẹ̀ Juda, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Israẹli. Joṣua sì run gbogbo wọn pátápátá àti ìlú wọn.

  3. Joṣua 11:22nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Kò sí ará Anaki kankan tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Israẹli: bí kò ṣe ní Gasa, Gati àti Aṣdodu.

  4. Joṣua 11:23nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, ó sì fi fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn. Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.

  5. Joṣua 12:1nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

  6. Joṣua 12:2nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.

  7. Joṣua 12:3nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.

  8. Joṣua 12:4nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.

  9. Joṣua 12:5nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe àkóso ní orí òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni.

  10. Joṣua 12:6nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

  11. Joṣua 12:7nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni sí òkè Halaki, èyí tí o lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:

  12. Joṣua 12:8nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi).

  13. Joṣua 12:9nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    Ọba Jeriko, ọ̀kan ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli), ọ̀kan

  14. Joṣua 12:10nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Jerusalẹmu, ọ̀kan ọba Hebroni, ọ̀kan

  15. Joṣua 12:11nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Jarmatu, ọ̀kan ọba Lakiṣi, ọ̀kan

  16. Joṣua 12:12nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Egloni, ọ̀kan ọba Geseri, ọ̀kan

  17. Joṣua 12:13nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Debiri, ọ̀kan ọba Gederi, ọ̀kan

  18. Joṣua 12:14nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Horma, ọ̀kan ọba Aradi, ọ̀kan

  19. Joṣua 12:15nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Libina, ọ̀kan ọba Adullamu, ọ̀kan

  20. Joṣua 12:16nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Makkeda, ọ̀kan ọba Beteli, ọ̀kan

  21. Joṣua 12:17nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Tapua, ọ̀kan ọba Heferi, ọ̀kan

  22. Joṣua 12:18nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Afeki, ọ̀kan ọba Laṣaroni, ọ̀kan

  23. Joṣua 12:19nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Madoni, ọ̀kan ọba Hasori, ọ̀kan

  24. Joṣua 12:20nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Ṣimroni-Meroni, ọ̀kan ọba Akṣafu, ọ̀kan

  25. Joṣua 12:21nǹkan bí 1450 ṣáájú Kristi

    ọba Taanaki, ọ̀kan ọba Megido, ọ̀kan