Fò sí àkóónú

Solomon

275 ẹsẹ · 27 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jedidiah

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Solomon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó láti inú ẹ̀yà Naftali àti tí baba rẹ̀ sì ṣe ará Tire, alágbẹ̀dẹ idẹ. Hiramu sì kún fún ọgbọ́n àti òye, àti ìmọ̀ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ idẹ. Ó wá sọ́dọ̀ Solomoni ọba, ó sì ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un.

  2. Ó sì túnṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwokòtò. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Solomoni ọba.

  3. ìkòkò, ọkọ́ àti àwokòtò. Gbogbo ohun èlò wọ̀nyí tí Hiramu ṣe fún Solomoni ọba nítorí iṣẹ́ Olúwa sì jẹ́ idẹ dídán.

  4. Solomoni sì jọ̀wọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí láìwọ́n, nítorí tí wọ́n pọ̀jù; bẹ́ẹ̀ ni a kò sì mọ ìwọ̀n idẹ.

  5. Solomoni sì túnṣe gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ń ṣe ti ilé Olúwa pẹ̀lú: pẹpẹ wúrà; tábìlì wúrà lórí èyí tí àkàrà ìfihàn gbé wà.

  6. Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.

  7. Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Israẹli jọ papọ̀, níwájú Solomoni ọba ní Jerusalẹmu, láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá láti ìlú Dafidi, tí ń ṣe Sioni.

  8. Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì pe ara wọn jọ sọ́dọ̀ Solomoni ọba ní àkókò àjọ ọdún ní oṣù Etanimu tí í ṣe oṣù keje.

  9. àti Solomoni ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rú ẹbọ.

  10. Nígbà náà ni Solomoni sì wí pé, “Olúwa ti wí pé, òun yóò máa gbé inú òkùnkùn biribiri.

  11. Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ Olúwa, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run.

  12. Nígbà tí Solomoni ti parí gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ yìí sí Olúwa tán, ó dìde kúrò lórí eékún rẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa níbi tí ó ti kúnlẹ̀ tí ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run

  13. Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.

  14. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.

  15. Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe,

  16. Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni.

  17. Lẹ́yìn ogún ọdún, nígbà tí Solomoni kọ́ ilé méjèèjì yìí tan: ilé Olúwa àti ààfin ọba.

  18. Solomoni ọba sì fi ogún ìlú ní Galili fún Hiramu ọba Tire, nítorí tí Hiramu ti bá a wá igi kedari àti igi firi àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.

  19. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn.

  20. Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri.

  21. Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ.

  22. Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀,

  23. àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.

  24. ìyẹn ni pé àwọn ọmọ wọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò le parun pátápátá, àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ẹrú fún títí di òní yìí.

  25. Ṣùgbọ́n, Solomoni kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Israẹli; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.