Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jesu tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé:

  2. Nígbà náà ni àwọn Farisi péjọpọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un.

  3. Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olóòtítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

  4. Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?”

  5. Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò?

  6. Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,

  7. ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?”

  8. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

  9. Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n fi í sílẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

  10. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè,

  11. Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ Ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run.

  12. Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.

  13. Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, àwọn Farisi pé ara wọn jọ.

  14. Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí.

  15. Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ.’

  16. Bí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé,

  17. “Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.”

  18. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,

  19. “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’

  20. Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

  21. Kò sí ẹnìkan tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ni ìdáhùn, kò tún sí ẹni tí ó tún bí i léèrè ohun kan mọ́ láti ọjọ́ náà mọ́.

  22. Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

  23. “Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín.

  24. Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run.

  25. Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi.