Fò sí àkóónú

David

968 ẹsẹ · 40 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan David

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Joabu sì dúró tì Amasa, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Joabu? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dafidi, kí ó máa tọ Joabu lẹ́yìn.”

  2. Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Efraimu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikri, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí Dafidi: fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.” Obìnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odi wá.”

  3. Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.

  4. Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa sì wí pé, “Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.”

  5. Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní Olúwa?”

  6. Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra Olúwa tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu.

  7. A sì ro èyí, tí Rispa ọmọbìnrin Aiah obìnrin Saulu ṣe, fún Dafidi.

  8. Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa.

  9. Ogun sì tún wà láàrín àwọn Filistini àti Israẹli; Dafidi sì sọ̀kalẹ̀, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bá àwọn Filistini jà, ó sì rẹ Dafidi.

  10. Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi.

  11. Ṣùgbọ́n Abiṣai ọmọ Seruiah ràn án lọ́wọ́, ó sì kọlu Filistini náà, ó sì pa á. Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì búra fún un pé, “Ìwọ kì yóò sì tún bá wa jáde lọ sí ibi ìjà mọ́ kí ìwọ má ṣe pa iná Israẹli.”

  12. Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á.

  13. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni ìran Rafa ní Gati, wọ́n sì ti ọwọ́ Dafidi ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

  14. Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu.

  15. “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀; ó sì fi àánú hàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”

  16. Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé,

  17. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.

  18. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò.

  19. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu, ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí àfonífojì Refaimu.

  20. Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà.

  21. Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.”

  22. Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá, òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa.

  23. Nínú àwọn ọgbọ̀n náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.

  24. Ìbínú Olúwa sì ru sí Israẹli, ó sì ti Dafidi sí wọn, pé, “Lọ ka iye Israẹli àti Juda!”

  25. Àyà Dafidi sì gbọgbẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí ó ka àwọn ènìyàn náà tán. Dafidi sì wí fún Olúwa pé, “Èmi ṣẹ̀ gidigidi ní èyí tí èmi ṣe, ṣùgbọ́n, èmi bẹ̀ ọ, Olúwa, fi ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì ní, nítorí pé èmi hùwà aṣiwèrè gidigidi!”