Fò sí àkóónú

David

968 ẹsẹ · 40 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan David

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

  2. Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!”

  3. Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.”

  4. Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ.

  5. Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

  6. Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ.

  7. Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú Olúwa títí láéláé.”

  8. Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili Olúwa, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká.

  9. Solomoni sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Olúwa nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga.

  10. Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.

  11. “Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi.

  12. Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”

  13. Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.

  14. “Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

  15. Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’

  16. Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”

  17. “Ní ti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀.

  18. Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa parí, ó mú gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá; fàdákà, wúrà àti ohun èlò, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Olúwa.

  19. Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli àti gbogbo àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àti àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Israẹli jọ papọ̀, níwájú Solomoni ọba ní Jerusalẹmu, láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá láti ìlú Dafidi, tí ń ṣe Sioni.

  20. Nígbà náà ni ó wí pé, “Ìbùkún ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ìlérí tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,

  21. ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti, èmi kò tí ì yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi láti wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n èmi ti yan Dafidi láti ṣàkóso àwọn Israẹli ènìyàn mi.’

  22. “Dafidi baba mi sì ní i lọ́kàn láti kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli.

  23. Ṣùgbọ́n Olúwa sì wí fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ ilé kan fún orúkọ mi, ó dára láti ní èyí ní ọkàn rẹ.

  24. “Olúwa sì ti pa ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe mọ́, èmi sì ti rọ́pò Dafidi baba mi, mo sì jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli báyìí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣèlérí, èmi sì kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.

  25. O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí.