Skip to content

Haggith

5 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Haggith

  1. Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali;

  2. Adonijah ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Haggiti sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì ṣètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀.

  3. Nígbà náà ni Natani béèrè lọ́wọ́ Batṣeba, ìyá Solomoni pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Adonijah, ọmọ Haggiti ti jẹ ọba láìjẹ́ pé Dafidi olúwa wa mọ̀ sí i?

  4. Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.”

  5. ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;