Skip to content

Geshur

9 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Geshurites

33.0000, 36.4100 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Geshur

  1. Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí.

  2. Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un; ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un.

  3. Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́.

  4. Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta.

  5. Joabu sì dìde, ó sì lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu wá sí Jerusalẹmu.

  6. Absalomu sì dá Joabu lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Geṣuri wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn ún síbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.”

  7. Nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan nígbà tí èmi ń bẹ ní Geṣuri ní Siria pé, ‘Bí Olúwa bá mú mi padà wá sí Jerusalẹmu, nítòótọ́, èmi ó sì sin Olúwa.’ ”

  8. (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi.

  9. ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un; ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti;