- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa War
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.
Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.
Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá; sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.
Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa.
A gbọ́ igbe ìpohùnréré ẹkún ní Sioni: ‘Àwa ti ṣègbé tó! A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”
Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa; ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.
Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já. Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́, kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́, tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi.
Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀, èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀. Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀ ni àwọn apanirun ti gorí, nítorí idà Olúwa yóò pa láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà; kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.
Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí. Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”
Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.
Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”
Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn Òkun lọ. Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn. Lójijì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni Olúwa wí.
Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn lójú ogun.
“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.
Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.
Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli?
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn wòlíì tí ó ṣáájú rẹ àti èmi ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ogun, ibi àti àjàkálẹ̀ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!