Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa War

639 ẹsẹ · 45 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. jáde lọ láti bá Bera ọba Sodomu, Birṣa ọba Gomorra, Ṣenabu ọba Adma, Ṣemeberi ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari) jagun.

  2. Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí, àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́.

  3. Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”

  4. Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì. Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.

  5. Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, àwọn olórí Moabu yóò wárìrì. Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù.

  6. Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta, títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa, títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.

  7. Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”

  8. Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú.

  9. Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín, wọn yóò sì tipa idà kú.

  10. Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn, àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000), àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.

  11. Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.

  12. Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́.

  13. Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà.

  14. Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè, Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro, àwọn ìlú yín ni a ó sì parun.

  15. Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un.

  16. Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.

  17. “ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín.

  18. Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín.

  19. Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run.

  20. Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.

  21. Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma.

  22. Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé, “…Wahebu ní Sufa, Òkun Pupa àti ní odò Arnoni

  23. Olúwa sọ fún Mose pé,

  24. “Gbẹ̀san lára àwọn Midiani fún àwọn ọmọ Israẹli. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”

  25. Wọ́n dojú ìjà kọ Midiani gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, kí wọn sì pa gbogbo wọn.