Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa War: God inflicts defeat in

14 ẹsẹ · 45 abala

Àwọn ẹsẹ nípa God inflicts defeat in

  1. Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.

  2. “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí, ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.

  3. Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.”

  4. Àwọn olórí Israẹli àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Olódodo ni Olúwa.”

  5. Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki.

  6. Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàrín sí sìn mí àti sí sin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.”

  7. Ní òpin ọdún, àwọn ọmọ-ogun Aramu yàn láti dojúkọ Joaṣi; wọ́n gbógun ti Juda àti Jerusalẹmu, wọ́n sì pa gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ènìyàn. Wọ́n rán gbogbo àwọn ìkógun sí ọba wọn ní Damasku.

  8. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ-ogun Aramu ti wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀ Olúwa sì fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ogun lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí Juda ti kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe ìdájọ́ Joaṣi.

  9. Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.

  10. Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà; ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.

  11. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé, “Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?” Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.

  12. Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀. Àwọn òkè sì wárìrì, òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro. Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò, ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.

  13. Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú? Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.

  14. Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn. Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára.’