Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa War: God threatens defeat in

22 ẹsẹ · 45 abala

Àwọn ẹsẹ nípa God threatens defeat in

  1. Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù, ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá. Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.

  2. A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú; láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn; Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé. “Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀, yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.”

  3. Ìránṣẹ́ tí ó ti lọ pe Mikaiah sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó dàbí ọ̀kan nínú tiwọn, kí o sì sọ rere.”

  4. Ṣùgbọ́n Mikaiah wí pe, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa ń bẹ láààyè, èmi yóò sọ ohun tí Ọlọ́run mi sọ.”

  5. Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Mikaiah, ṣe kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Ramoti Gileadi, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?” Ó sì dáhùn pé, “Ẹ dojúkọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun, nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”

  6. Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?”

  7. Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”

  8. Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí: “Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.

  9. Ẹ̀yin wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’ Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá! Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’ Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!

  10. Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”

  11. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bí mo ṣe sọ igi àjàrà tó wà láàrín àwọn igi inú igbó yòókù di igi ìdáná, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe ṣe gbogbo ènìyàn tó ń gbé Jerusalẹmu.

  12. Èmi yóò dojúkọ wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti jáde kúrò nínú iná kan, síbẹ̀ iná mìíràn yóò pàpà jó wọn. Nígbà tí mo bá sì dojúkọ wọ́n, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.

  13. Èmi yóò sọ ilé náà di ahoro nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn, ni Olúwa Olódùmarè wí.”

  14. “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé, “ ‘Idà kan, idà kan, tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú,

  15. a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.

  16. “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbámú; a pọ́n ọn, a sì dán an, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.

  17. Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi; yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà; nítorí náà lu oókan àyà rẹ.

  18. “ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’

  19. “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́. Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún.

  20. Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun. Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun.

  21. Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ.

  22. Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”