Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa War: Famine
Àwọn ẹsẹ nípa Famine
Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ— ta ni yóò tù ọ́ nínú? Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.
Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò, ebi sì yó wa bí àárẹ̀.