Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa War: God in

47 ẹsẹ · 45 abala

Àwọn ẹsẹ nípa God in

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fi fún un yín lónìí, àwọn ará Ejibiti ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́.

  2. Olúwa yóò jà fún un yín; kí ẹ̀yin kí ó sá à mu sùúrù.”

  3. Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń ṣáájú yín yóò jà fún un yín; bí ó ti ṣe fún un yín ní Ejibiti lójú ẹ̀yin tìkára yín

  4. Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Joṣua pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.

  5. Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”

  6. Ẹ lè máa rò láàrín ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”

  7. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, ẹ rántí dáradára ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe sí Farao àti gbogbo Ejibiti.

  8. Ẹ sá à fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. Olúwa Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.

  9. Pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrín wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sá pamọ́ fún un yín, yóò fi ṣègbé.

  10. Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  11. Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò nígbà yín láààyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko igbó má ba à gbilẹ̀ sí i láàrín yín.

  12. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run.

  13. Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run.

  14. Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ.

  15. Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”

  16. Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má ṣe bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú rẹ, Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

  17. Nígbà náà ni Mose pe Joṣua ó sì wí fún un níwájú gbogbo Israẹli pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrín wọn bí ogún wọn.

  18. Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ; kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”

  19. Olúwa sì fún Joṣua ọmọ Nuni ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Israẹli wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.”

  20. Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!

  21. Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún (1,000), tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá, bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n, bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

  22. Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose,

  23. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

  24. “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

  25. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.