Skip to content

Lachish

22 verses

31.5600, 34.8400 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Lachish

  1. Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe,

  2. Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.

  3. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú àwọn ọba márààrún náà kúrò nínú ihò àpáta, àwọn ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni.

  4. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo ará Israẹli, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Libina lọ sí Lakiṣi; ó sì dó tì í, ó sì kọlù ú.

  5. Olúwa sì fi Lakiṣi lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sì gbà á ní ọjọ́ kejì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pa gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Libina.

  6. Ní àkókò yìí, Horamu ọba Geseri gòkè láti ran Lakiṣi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Joṣua ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀.

  7. Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lakiṣi lọ sí Egloni; wọ́n sì dó tì í, wọ́n sì kọlù ú.

  8. Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lakiṣi.

  9. ọba Jarmatu, ọ̀kan ọba Lakiṣi, ọ̀kan

  10. Lakiṣi, Boskati, Egloni,

  11. Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀.

  12. Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah ọba Juda sì ránṣẹ́ yìí sí ọba Asiria ní Lakiṣi, wí pé, “Mo ti ṣẹ̀, padà lẹ́yìn mi: èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba Asiria sì bu fún Hesekiah ọba Juda ọ̀ọ́dúnrún (300) tálẹ́ǹtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ǹtì wúrà.

  13. Ọba Asiria rán alákòóso gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun tí ó pọ̀, láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Wọ́n wá sí òkè Jerusalẹmu wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá alágbàfọ̀.

  14. Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Libina jà.

  15. Adoraimu, Lakiṣi, Aseka

  16. Láti ìgbà tí Amasiah ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa, wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀.

  17. Lẹ́yìn ìgbà tí Sennakeribu ọba Asiria àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lakiṣi. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Hesekiah ọba Juda àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí ó wà níbẹ̀:

  18. Sanoa, Adullamu àti àwọn ìletò o wọn, ní Lakiṣi àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Aseka àti àwọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Beerṣeba títí dé àfonífojì Hinnomu.

  19. Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá alágbàfọ̀,

  20. Nígbà tí ọ̀gágun gbọ́ pé ọba Asiria ti fi Lakiṣi sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn, ó sì bá ọba tí ń bá Libina jà.

  21. Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda.

  22. Ìwọ olùgbé Lakiṣi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Sioni, nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.