Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trees

132 ẹsẹ · 87 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké, Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.

  2. Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.

  3. Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀, àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀, àwọn tí idà ti gún, àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun. Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,

  4. Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá, wá igi tí kò le è rà. Ó wá oníṣọ̀nà tí ó láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

  5. Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀

  6. Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù, àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.

  7. Ó gé igi kedari lulẹ̀, tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù. Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó, ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.

  8. Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.

  9. Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”

  10. Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀; ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín. Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé, “Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”

  11. Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú, kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye láti sọ wí pé, “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná; mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀, mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí? Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”

  12. Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà, àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ. Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa, fún àmì ayérayé, tí a kì yóò lè parun.”

  13. Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ Olúwa sọ wí pé, “Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé, “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

  14. àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

  15. Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́.

  16. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?” Mo sì dáhùn wí pé, “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

  17. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká. Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò, nítorí pé ó kún fún ìninilára.

  18. Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti ère Aṣerah lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga.

  19. Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

  20. “Ọmọ ènìyàn, báwo ni igi àjàrà ṣe dára ju igi mìíràn lọ tàbí jù ẹ̀ka àjàrà tó wà láàrín igi yòókù nínú igbó?

  21. Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi kedari tó ga jùlọ,

  22. “ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.

  23. Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkúrú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé. “ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì ṣe e.’ ”

  24. Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.

  25. Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bò ó mọ́lẹ̀; tàbí kí àwọn igi junifa ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.