Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trees: Sycamore
Àwọn ẹsẹ nípa Sycamore
Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti igi kedari ni ó ṣe kí ó dàbí igi sikamore tí ń bẹ ní àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́.
Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore.
Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.