Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trees: For fuel

4 ẹsẹ · 87 abala

Àwọn ẹsẹ nípa For fuel

  1. Ó gé igi kedari lulẹ̀, tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù. Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó, ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.

  2. Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn; díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́, ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín; ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.

  3. Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná; lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀, ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó. Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé, “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”

  4. Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò ge lulẹ̀ ti a ó sì wọ jù sínú iná.