Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trees: Apple

3 ẹsẹ · 87 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Apple

  1. Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó, ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin. Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀, èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.

  2. Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀. Olólùfẹ́ Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.

  3. Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.