Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Second Coming of Christ

144 ẹsẹ · 65 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí mo bá sì lọ láti pèsè ààyè sílẹ̀ fún un yín, èmi ó tún padà wá, èmi ó sì mú yín lọ sọ́dọ̀ èmi tìkára mi; pé níbi tí èmi gbé wà, kí ẹ̀yin lè wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

  2. Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn.

  3. Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn.

  4. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”

  5. Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

  6. àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu.

  7. Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀.

  8. Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́.

  9. Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

  10. Nítorí a ó sọ ẹ̀dá tìkára rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú ẹrú ìdíbàjẹ́, sí òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

  11. Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀.

  12. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

  13. Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi.

  14. Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  15. Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

  16. Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun.

  17. Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé.

  18. Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run, láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa.

  19. Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

  20. Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí.

  21. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.

  22. àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.

  23. Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

  24. Nítorí pé, Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde.

  25. Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé.