Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Second Coming of Christ: Accompanied by Angels
Àwọn ẹsẹ nípa Accompanied by Angels
Nítorí Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
“Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run.
Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ Ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá padà dé nínú ògo Baba rẹ̀, pẹ̀lú àwọn angẹli mímọ́.”
Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára.