Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Christ Jesus: Mission of Jesus

72 ẹsẹ · 25 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Mission of Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

  2. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

  3. “Èmi, Olúwa, ti pè ọ́ ní òdodo, Èmi yóò di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́ láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn àti ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà

  4. láti la àwọn ojú tí ó fọ́, láti tú àwọn òǹdè kúrò nínú túbú àti láti tú sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n àwọn tí ó jókòó nínú òkùnkùn.

  5. Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi nítorí Olúwa ti fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn tálákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

  6. láti kéde ọdún ojúrere Olúwa àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

  7. àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

  8. Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀.

  9. Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,

  10. “Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín.

  11. Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

  12. “Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà.

  13. Nítorí èmi wá láti ya “ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀, ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀, àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ.

  14. Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

  15. For the Son of man is come to save that which was lost.

  16. “Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí?

  17. Ǹjẹ́ bí òun bá sì wá á rí i, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin kò mọ̀ pé inú rẹ̀ yóò dùn nítorí rẹ̀ ju àwọn mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò nù lọ?

  18. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni kì í ṣe ìfẹ́ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, pé ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kí ó ṣègbé.

  19. Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e.

  20. Nígbà tí àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èétirí tí ó fi ń bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”

  21. Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

  22. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀. Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

  23. Jesu dáhùn wí pé, “Báwo ni àwọn àlejò ọkọ ìyàwó yóò ṣe máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó ṣì wà lọ́dọ̀ wọn?

  24. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ ọjọ́, a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn. Nígbà náà wọn yóò gbààwẹ̀ ni ọjọ́ wọ̀nyí.”

  25. “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, bí ó ba ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tuntun tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fàya kúrò lára ògbólógbòó, yíya rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù.