Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Christ Jesus: Perfections of (Not classified under foregoing topics)

6 ẹsẹ · 25 abala

Wá "The Christ Jesus"

Àwọn ẹsẹ nípa Perfections of (Not classified under foregoing topics)

  1. Àwọn ará Ninefe yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Jona wà níhìn-ín yìí.

  2. Ọbabìnrin gúúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Solomoni. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni ń bẹ níhìn-ín yìí.

  3. Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù.

  4. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.” Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”

  5. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.

  6. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.”