Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shepherd

48 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi.

  2. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.

  3. Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.”

  4. Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.”

  5. Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.”

  6. Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.”

  7. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.”

  8. Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà.

  9. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi.

  10. “Mo ti wà lọ́dọ̀ rẹ fún ogún ọdún, àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ rẹ kò sọnù bẹ́ẹ̀ n kò pa ọ̀kan jẹ rí nínú àwọn àgbò rẹ.

  11. Èmi kò mú ọ̀kankan wá fún ọ rí nínú èyí tí ẹranko búburú fàya, èmi ni ó fi ara mọ́ irú àdánù bẹ́ẹ̀. Ẹrankẹ́ran tí wọ́n bá sì jí lọ, lọ́sàn án tàbí lóru, ìwọ ń gba owó rẹ̀ lọ́wọ́ mi.

  12. Báyìí ni mo wà; oòrùn ń pa mi lọ́sàn án, òtútù ń pa mi lóru, mo sì ń ṣe àìsùn.

  13. ẹ fún un lésì pé, ‘Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn ni láti ìgbà èwe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.’ Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láààyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé àwọn ará Ejibiti kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.”

  14. Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.

  15. Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhìn-ín yìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa.

  16. Ṣùgbọ́n Dafidi sọ fún Saulu pé, “Ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ti ń tọ́jú agbo àgùntàn baba rẹ̀. Nígbà tí kìnnìún tàbí àmọ̀tẹ́kùn bá wá láti wá gbé àgùntàn láti inú igbó.

  17. Mo sá tẹ̀lé e, mo lù ú, mo sì gba àgùntàn náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tí ó kọjú sí mi, mo fi irun rẹ̀ gbá a mú, mo sì lù ú mo sì pa á.

  18. Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà.

  19. “Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli.

  20. Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.

  21. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.

  22. Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù, Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́,

  23. Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran; ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.

  24. Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

  25. Wí fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mí fẹ́, níbo ni ìwọ ń da agbo ẹran lọ. Níbi tí ìwọ mú agbo ẹran rẹ sinmi ní ọ̀sán, kí ni ìdí tí èmi yóò fi jẹ́ obìnrin asán ní ẹ̀bá agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.