Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shepherd

48 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’

  2. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi.

  3. Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni Olúwa wí.

  4. Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”

  5. Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

  6. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́.

  7. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.

  8. Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

  9. Angẹli náà sì wí fún wọn pé, “Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.

  10. Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tí í ṣe Kristi Olúwa.

  11. Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.”

  12. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,

  13. “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti ní ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”

  14. Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.”

  15. Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.

  16. Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.

  17. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.

  18. Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.

  19. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.

  20. “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà.

  21. Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀, ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde.

  22. Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.

  23. Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.”