Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shem

81 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.

  2. Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  3. Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi.

  4. Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  5. Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.

  6. Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  7. Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu.

  8. Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

  9. Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.

  10. Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  11. Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra.

  12. Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  13. Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani.

  14. Wọ̀nyí ni ìran Tẹra. Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani. Harani sì bí Lọti.

  15. Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea.

  16. Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska.

  17. Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

  18. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. Àwọn ọmọ Aramu: Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.

  19. Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.

  20. Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.

  21. Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.

  22. Hadoramu, Usali, Dikla,

  23. Ebali, Abimaeli, Ṣeba.

  24. Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.

  25. Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,