Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shem: Descendants of

70 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Descendants of

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èyí ni ìran àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.

  2. A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.

  3. Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.

  4. Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri àti Meṣeki.

  5. Arfakṣadi sì bí Ṣela, Ṣela sì bí Eberi.

  6. Eberi sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.

  7. Joktani sì bí Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera.

  8. Hadoramu, Usali, Dikla,

  9. Obali, Abimaeli, Ṣeba.

  10. Ofiri, Hafila àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.

  11. Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa títí dé Sefari, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà-oòrùn.

  12. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣemu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

  13. Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu. Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Arfakṣadi.

  14. Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  15. Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùndínlógójì ni ó bí Ṣela.

  16. Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

  17. Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.

  18. Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  19. Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi.

  20. Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  21. Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.

  22. Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

  23. Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu.

  24. Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

  25. Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.