Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings

802 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

  2. Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”

  3. A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

  4. A kò le è fi wúrà Ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta safire díye lé e.

  5. Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.

  6. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.

  7. Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

  8. Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?

  9. A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

  10. Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

  11. Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.

  12. Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

  13. láti dà òsùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òsùwọ̀n wọ́n omi.

  14. Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

  15. nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

  16. Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

  17. Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú, ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.

  18. Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.

  19. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

  20. Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú! Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

  21. Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

  22. Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo, ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

  23. Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

  24. Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.

  25. Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”