Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings: The majesty of God

19 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The majesty of God

  1. Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?

  2. Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn.

  3. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.

  4. Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.

  5. Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn; ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú.

  6. Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

  7. Ipa rẹ̀ gba Òkun, ọ̀nà rẹ̀ ń bẹ nínú Òkun, ọ̀nà la omi alágbára kọjá ipa rẹ̀ ń bẹ nínú líla omi alágbára kọjá, nítòótọ́ a kò rí ojú ẹsẹ̀ rẹ̀.

  8. Ó tọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.

  9. Ọlọ́run yóò wa láti Temani, ibi mímọ́ jùlọ láti òkè Parani ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ.

  10. Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

  11. Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ; ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

  12. Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

  13. Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.

  14. Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn odò nì, Olúwa? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun tí ìwọ fi ń gun ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?

  15. A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.

  16. Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ; ibú ń ké ramúramù ó sì gbé irú omi sókè.

  17. Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

  18. Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.

  19. Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là, Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀.