Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Select Readings: The brevity of life
Àwọn ẹsẹ nípa The brevity of life
“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin, ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,
síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù, àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.